Ìwé Wòlíì Àìsáyà 57:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀; a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì sí ẹni tó yé pé a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.

2Gbogbo àwọn tí ń rìn déédéé ń wọ inú àlàáfíà; wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn lókùú.

2

3“Ṣùgbọ́n ìwọ wá níhìnín, ìwọ ọmọ àjẹ́ yìí, ìwọ ìran panṣágà àti aṣẹ́wó!

4Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà? Ta ni o ń yọ ṣùtì sí tí o sì yọ ahọ́n síta? Ẹ̀yin kì í haá ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí, àti ìràn àwọn òpùrọ́?

5Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrin igi óákù àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀; ẹ fi àwọn ọmọ yín rúbọ nínú kòtò jínjìn àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.

6Àwọn ère tí ó wà ní àárin òkúta dídán wọ̀n n nì, nínú kòtò jínjìn ni ìpín in yín; àwọn, àwọ̀n ni ìpín in yín. Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀ àti láti ta ọrẹ oníhóró. Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ kí n dáwọ́ dúró?

7Ìwọ ti ṣe bẹ́ẹ̀dì rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà; níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.

8Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn àmì òrìṣà yín sí. Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sí bẹ́ẹ̀dì yín sílẹ̀, ẹ gun oríi rẹ̀ lọ, ẹ sì sí i sílẹ̀ gbagada; ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn bẹ́ẹ̀dì wọn, ẹ̀yin sì ń wo ìhòòhò wọn.

9Ẹ̀yin lọ sí Mólẹ́kì pẹ̀lú òróró ólífì ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín. Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré; ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!

10Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ baa yín, ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’ Ẹ rí okun kún agbára yín, nípá bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ọ yín.

10

11“Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù tí ẹ fi ń ṣèké sí mi, àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín? Ǹjẹ́ kì í ṣe nítoríi dídákẹ jẹ́ ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́ tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?

12Èmi yóò sí òdodo yín payá àti iṣẹ́ẹ yín, wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.

13Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín! Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ, èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀ ni yóò jogún ilẹ̀ náà yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

14A ó sì sọ wí pé: “Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe! Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

15ⓐ Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́: “Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

16Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé, tàbí kí n máa bínú ṣá á, nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóò rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi èémí ọmọnìyàn tí mo ti dá.

17Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀; mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínú ṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.

18Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn; Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,

19ⓑ ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Ísírẹ́lì. Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,” ni OLÚWA wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”

20Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkun tí kò le è sinmi, tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.

21“Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

le>