Ìwé Wòlíì Àìsáyà 6:1-13 BYB2014 - Bible AI

1Ní ọdún tí ọba Hùṣáyà kú, mo rí OLÚWA tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ọ̀wọ́ aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ḿpìlì.

2Àwọn Ṣéráfù wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹṣẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò.

3ⓐ Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:

3“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

4ⓑ Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹ́ḿpìlì sì kún fún èéfín.

5“Ègbé ni fún mi!” Ni mo ké, “Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrin àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

6Lẹ́yìn náà, ọ̀kan nínú àwọn Ṣéráfù wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ́-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní oríi pẹpẹ.

7Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wòó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

8Lẹ́yìn náà, mo sì gbọ́ ohùn OLÚWA wí pé, “Ta ni n ó rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?” Èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

9ⓒ Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn mi lọ kí o sì wí pé; “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín; ní rírí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’

10Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì, mú kí wọn kútí kí o sì pa ojú wọn dé. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ojú u wọn ríran, ki wọn má ba à fi etíi wọn gbọ́ràn, kí òye máa ba à yé wọn ní ọkàn an wọn kí wọn má ba à yípadà kí a má ba à sì wò wọ́n sàn.”

11Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó OLÚWA?” Òun sì dáhùn pé: “Títí tí gbogbo ìlú ńlá yóò fi dahoro láìsí olùgbé nínú un rẹ̀ mọ́, títí tí gbogbo ilé yóò fi di ìkọ̀sílẹ̀ tí gbogbo ilé yóò sì di àlàpà àti ahoro,

12títí tí OLÚWA yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátapáta.

13Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà, yóò sì tún pàpà padà parun Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹ́rẹ́bíńtì àti óákù ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”

e>