Ìwé Wòlíì Àìsáyà 61:1-11 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ẹ̀mí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wà lára mi nítorí OLÚWA ti fi àmì-òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn talákà. Ó ti rán mi láti ṣe àwòtan oníròbìnújẹ́ láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,

2Láti kéde ọdún ojúrere OLÚWA àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa, láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,

3àti láti pèṣè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Ṣíhónì láti dé wọn ládé ẹ̀yẹ dípò eérú, òróró ìdùnnú dípò ìbànújẹ́, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúùru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní óákù òdodo, irúgbìn OLÚWA láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

3

4Wọn yóò tún àwọn ahoro ìṣẹ̀ǹbáyé kọ́ wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́tijọ́ náà bọ̀ sípò; wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.

5Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ; àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.

6A ó sì máa pè yín ní àlùfáà OLÚWA, a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa. Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.

6

7Dípò àbùkù wọn àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po-méjì, àti dípò àbùkù wọn wọn yóò yọ̀ nínú ìníi wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn, ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ ti wọn.

7

8“Nítorí Èmi, OLÚWA fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo; mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀ Ní òtítọ́ mi èmi yóò ṣẹ̀san fún wọn èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúu wọn.

9A ó mọ ìrandíran wọn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ìran wọn láàrin àwọn ènìyàn Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí OLÚWA ti bùkún.”

9

10Èmi yọ̀ gidigidi nínú OLÚWA; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe oríi rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

11Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú èhù jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀ èdè.

le>