1Nítorí Ṣíhónì èmi kì yóò dákẹ́,nítorí i Jérúsálẹ́mù èmi kì yóò sinmi ẹnu,títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,àti ìgbàlà rẹ̀ bí i tọ́ọ̀sì tí ń jó geregere.
2ⓐ Àwọn orílẹ̀ èdè yóò rí òdodo rẹ,àti gbogbo ọba ògo rẹa ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìírànèyí tí ẹnu OLÚWA yóò fi fún un.
3Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ OLÚWA,adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.
4Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà,àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà;nítorí OLÚWA yóò yọ́nú sí ọàti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.
5Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwóbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwóGẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ.
5
6Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù;wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.Ẹ̀yin tí ń ké pe OLÚWA,ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi,
7àti kí ẹ má ṣe fún òun pẹ̀lú ní ìsinmitítí tí yóò fi fi ìdí Jérúsálẹ́mù múlẹ̀tí yóò sì fi òun ṣe ìyìn orí ilẹ̀ ayé.
7
8OLÚWA ti búra pẹ̀lú ọ̀tún rẹ̀àti nípa agbára apá rẹ:“Èmi kì yóò jẹ́ kí hóró rẹdi oúnjẹ fún ọ̀tá rẹbẹ́ẹ̀ ni àwọn àjèjì kì yóò mu wáìnìtuntun rẹ mọ́èyí tí ìwọ ti ṣe làálàá fún;
9ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá kóórè rẹ̀ ni yóò jẹ ẹ́tí wọn ó sì yin OLÚWA,àti àwọn tí wọ́n bá kó gírépù jọ ni wọn ó mú unnínú àgbàlá ilé mímọ́ mi.”
9
10Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà!Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn.Ẹ mọ ọ́n, ẹ mọ ojú ọ̀nà òpópó!Ẹ sa òkúta kúròẸ gbé àṣíá ṣókè fún àwọn orílẹ̀ èdè
10
11OLÚWA ti ṣe ìkédetítí dé òpin ilẹ̀ ayé:“Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Ṣíhónì pé,‘kíyèsí i, Olùgbàlà rẹ ń bọ̀!Kíyèsí i, èrè ń bẹ pẹ̀lúu rẹ̀,àti ẹ̀san rẹ pẹ̀lú n tẹ̀lé e lẹ́yìn.’ ”
12A ó sì pè wọ́n ní Ènìyàn Mímọ́,ẹni ìràpadà OLÚWA;a ó sì máa pè ọ́ ní ìwákiri,Ìlú tí a kì yóò kọ̀ sílẹ̀.