1Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá, tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
2Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó tí ó sì mú kí omi ó hó, ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹ kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
3Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí, o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.
4ⓐ Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ, kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ, tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
5Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ayọ̀ ṣe ohun tótọ́, tí ó rántí ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn, inú bí ọ. Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
6Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkíṣà ẹlẹ́gbin; gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
7Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú; nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
7
8Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, OLÚWA, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni ọ̀mọ; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
9Má ṣe bínú kọjá ààlà, Ìwọ OLÚWA: Má ṣe rántíi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
10Àwọn Ìlú Mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀; Ṣíhónì pàápàá aṣálẹ̀ ni, Jérúsálẹ́mù ibi ìkọ̀sílẹ̀.
11Tẹ́ḿpìlì Mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
12Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, OLÚWA, ìwọ ó ha sì tún fara rẹ pamọ́ bí? Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹwá kọjá ààlà bí?