Ìwé Wòlíì Àìsáyà 66:1-24 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìṣẹ mi, Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà? Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

2Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni OLÚWA wí.

2“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹrarẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi.

3Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rúbọ ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́ àgùntàn kan tọrẹ, dàbí ẹni tí ó kán ajá kan lọ́rùn; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbin oníhóró tọrẹ dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá, ẹni tí ó bá sì ṣun tùràrí ìrántí, dàbí ẹni tí ó sin ère òrìṣà. Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tiwọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;

4Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tísílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kóríìra rẹ̀.”

4

5Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kóríra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin OLÚWA lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

6ⓑ Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá! Ariwo tí OLÚWA ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn.

6

7ⓒ “Kí ó tó lọ sí ìrọbí, ó ti bímọ; kí ó tó di pé ìrora dé bá a, ó ti bí ọmọkùnrin.

8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kan tàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan? Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbí bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bí kí èmi má sì mú ni bí?” ni OLÚWA wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” ni Ọlọ́run yín wí.

10“Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀; ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.

11Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára; Ẹ̀yin yóò mu àmuyó ẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

12Nítorí ohun tí OLÚWA wí nìyìí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

13Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”

13

14Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ OLÚWA ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15Kíyèsí i, OLÚWA ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle; òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

16Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí OLÚWA yóò pa.

17“Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni OLÚWA wí.

18“Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.

19“Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè Táṣíṣì, sí àwọn ará Líbíyà àti Lídíyà (ti a mọ̀ sí atamọ́tàsé), sí Túbálì ati ará Gíríkì, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnàréré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

20Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀ èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí OLÚWA lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti wágùnnù, àti lórí ìbáaka àti ràkúnmí,” ni OLÚWA wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú tẹ́ḿpìlì OLÚWA nínú ohun èlò mímọ́.

21Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Léfì,” ni OLÚWA wí.

22ⓓ “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe faradà á níwájú mi,” ni OLÚWA wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé.

23Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọnìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni OLÚWA wí.

24ⓔ “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”

le>