1OLÚWA sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi pẹ́ẹ́nì lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì:
2Èmi yóò sì pe Hùráyà, Àlùfáà àti Ṣekaráyà ọmọ Jébérékíà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbọ́kànlé fún mi.
3Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì-obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. OLÚWA sì wí fún mi pé, “pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì.
4Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Dámásíkù àti ìkógun ti Ṣamáríà ni ọba àwọn Áṣíríà yóò ti kó lọ.”
5OLÚWA sì tún sọ fún mi pé:
6
7
8
9
10
11OLÚWA bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:
12
13
14
15
16
17
18Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí OLÚWA fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òké Síhónì.
19Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn Oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè?
20Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ní ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.
21Pẹ̀lú ìpọ́njú àti ebi, ni wọn yóò máa rin ilẹ̀ náà ká, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni inú yóò bí wọn, wọn yóò síjú wòkè, wọn yóò sì ṣépè lé àwọn ọba àti ọlọ́run wọn.
22Nígbà náà ni wọn yóò síjú wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúúrù tí ó bani lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.