Ìwé Wòlíì Ámósì 1:1-15 BYB2014 - Bible AI

1Àwọn ọ̀rọ̀ Ámósì, ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn Tékóà; ohun tí o rí nípa Ísírẹ́lì ní ọdun méjì ṣáàjú ilẹ̀ riri, nígbà tí Úsáyà ọba Júdà àti Jéróbóámù ọmọ Jéóhásì jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.

2ⓐ Ó wí pé: “OLÚWA yóò bú jáde láti Síóní ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jérúsálẹ́mù wá; Ibùgbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, Orí-òkè Kámẹ́lì yóò sì rọ.”

3ⓑ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Dámásíkù, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi pada Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gílíádì. Pẹ̀lú ohun èlo irin tí ó ní eyín mímú

4Èmi yóò rán iná sí ilé Hásáélì Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Bẹni-Hádádì run.

5Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdáàbú Dámásíkù; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áfénì run Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Bẹti-Édénì. Àwọn ará a Árámù yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kírì,” ni OLÚWA wí.

6ⓒ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Gásà, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Gẹ́gẹ́ bí í oníṣòwò ẹrú, ó kó gbogbo àwọn ènìyàn mi ní ìgbékùn. Ó sì tà wọ́n fún Édómù,

7Èmi yóò rán iná sí ara odi Gásà tí yóò jó gbogbo ààfin rẹ̀ run

8Èmi yóò ké àwọn olùgbé Ásódì kúrò. Àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé ní Ákélónì mú. Èmi yóò yí ọwọ́ mi sí Ékírónì títí tí ìyókù Fílístínì yóò fi ṣègbé,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí.

9ⓓ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Tírè àní nítorí mẹ́rin, Èmi kì yóò yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Nítorí wọ́n ta gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìgbékùn fún Édómù Wọn kò sì nán-án-ní májẹ̀mú ọbàkan,

10Èmi yóò rán iná sí ara odi Tírè Tí yóò jó gbogbo àwọn ààfin rẹ̀ run.”

11ⓔ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Édómù, àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀, Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́

12Èmi yóò rán iná sí orí Témánì Tí yóò jó gbogbo ààfin Bósírà run.”

13ⓕ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ámónì àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.

14Èmi yóò rán iná sí ara odi Rábà Èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run pẹ̀lú igbe ní ọjọ́ ogun pẹ̀lú ìjì ní ọjọ́ ààjà

15Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn Òun àti àwọn ọmọ aládé rẹ̀ lápapọ̀,” ni OLÚWA wí.

>