Ìwé Wòlíì Ámósì 2:1-16 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Èyí ni ohun tí OLÚWA wí; “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Móábù, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà, Nítorí ó ti sun-ún, di eérú, egungun ọba Édómù

2Èmi yóò rán iná sí orí Móábù Èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kéríótì run. Móábù yóò sì kú pẹ̀lú ariwo pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè

3Èmi yóò ké onídájọ́ rẹ̀ kúrò Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ aládé rẹ́ nínú rẹ̀,” ni OLÚWA wí;

4Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Júdà, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn ti kọ òfin OLÚWA sílẹ̀ wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́ Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà Òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé

5Èmi yóò rán iná sí orí Júdà Èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jérúsálẹ́mù run.”

6Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Ísírẹ́lì àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.

7Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn talákà mọ́lẹ̀ bí wọ́n ti ń tẹ ẹrùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n sì fi òtítọ́ du àwọn tí a ni lára Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúndíá kan náà Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́

8Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bá a pẹpẹ Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtanràn.

8

9“Mo pa àwọn ará Ámórì run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi Kédárì. Òun sì le koko bí igi Óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìṣàlẹ̀ wá.

9

10“Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, mo sì sìn yín la ihà já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Ámórì fún un yín.

11Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàárin àwọn ọmọ yín àti láàárin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Násárátì èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Ísírẹ́lì?” ni OLÚWA wí.

12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Násárátì ní ọtí mu Ẹ sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

12

13“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.

14Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

15tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

16àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòòhò ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí.

>