Ìwé Wòlíì Ámósì 3:1-15 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Éjíbítì:

2“Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ níyà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”

3Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti gbà láti ṣe é?

4Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbo, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú?

5Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?

6Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wú ìlú kò ha ṣe OLÚWA ni ó fà á?

6

7ⓐ Nítòótọ́ OLÚWA Ọlọ́run kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.

7

8Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? OLÚWA Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọtẹ́lẹ̀?

8

9Ẹ kéde ní ààfin Áṣídódù àti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samáríà; Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrin rẹ̀ àti ìnílára láàrin àwọn ènìyàn rẹ.”

9

10“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni OLÚWA wí, “Ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”

11Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”

12Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ń gbé Samáríà kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”

13“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù,” ni OLÚWA wí, OLÚWA Ọlọ́run alágbára.

14“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.”

15“Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀ẹ̀rùn; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni OLÚWA wí.

>