Ìwé Wòlíì Ámósì 4:1-13 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Báṣánì lórí òkè Samáríà, ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni talákà lára, tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”

2OLÚWA Ọlọ́run ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra: “Àkókò náà yóò dé nítòótọ́ nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ, ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.

3Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ gba àárin odi yíya a ó sì lé e yín sí Hámónà,” ni OLÚWA wí.

4“Ẹ lọ sí Bétélì láti dẹ́ṣẹ̀; ẹ lọ sí Gílígálì kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i. Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá, ìdámẹ́wàá yín ní ọdọdún mẹ́ta.

5Kí ẹ mú ọrẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun tí a sun kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá lọ fi wọ́n yagàn, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí.

5

6“Èmi fún un yín ní inú òfìfo ní gbogbo ìlú àti láìní àkàrà ní gbogbo ibùgbé yín, ṣíbẹ̀, ẹ̀yin kò tí ì yípadà sími,” ni OLÚWA wí.

6

7“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta. Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn. Oko kan ní òjò; àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ.

8Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ibòmíràn fún omi wọn kò rí àrító láti mú, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLÚWA wí.

8

9“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo lu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi àrá àti ìrì lù wọ́n. Esú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi ólífì yín, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLÚWA wí.

9

10“Mo rán àjàkálẹ̀-àrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Éjíbítì. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbékùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLÚWA wí.

10

11“Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fò yọ kúrò nínú ìjóná, ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni OLÚWA wí.

11

12“Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Ísírẹ́lì, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Ísírẹ́lì.”

12

13Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. OLÚWA Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni orúkọ rẹ̀.

>