1Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
2“Wúndíá Ísírẹ́lì ṣubúláì kò sì le padà dìdeó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀kò sí ẹni tí yóò gbé e nàró.”
3Èyí ni ohun tí OLÚWA ọ̀gá ògo wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde,yóò dín ku ọgọ́run ní Ísírẹ́lì.Ìlú tí ọgọ́run alàgbà ti jádeyóò ṣẹ́ku ẹni mẹ́wàá.”
4Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ fún ilé Ísírẹ́lì: “Wá mi kí o sì yè;
5Ẹ má ṣe wá Bẹ́tẹ́lì,Ẹ má ṣe lọ sí GílígálìẸ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Bíáṣébà.Nítorí dájúdájú a ó kó Gílígálì ní ìgbèkùnA ó sì sọ Bẹ́tẹ́lì di asán.”
6Ẹ wá OLÚWA, ẹ̀yin yóò sì yè,Kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Jósẹ́fùA sì jó o runBẹ́tẹ́lì kò sì ní rí ẹni tí yóò bomi pa á.
6
7Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkoròTí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀
8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Píláédì àti ÓríónìẸni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀Tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹẸni tí ó wọ́ omi òkun jọpọ̀Tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀OLÚWA ni orúkọ rẹ̀,
9Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódiTí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ aládé di ahoro
10Ìwọ kórìíra ẹni tí ń ṣòdì ní ẹnu ibodèó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́
10
11Ìwọ ń tẹ talákà mọ́lẹ̀o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọnNítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́léṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọnNítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn
12Nítorí mo mọ iye àìṣedédé rẹmo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
12Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du talákà ní ilé ẹjọ́
13Àwọn ọlọgbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyíNítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
13
14Wá rere, má ṣe wá búburúkí ìwọ ba à le yèNígbà náà ni OLÚWA alágbára yóò wà pẹ̀lú ù rẹ.Òun yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ bí ìwọ ṣe wí
15Kòrìírà búburú kí o sì fẹ́ rereDúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́Bóyá OLÚWA Ọlọ́run alágbárayóò síjú àánú wo ọmọ Jósẹ́fù tó ṣẹ́kù
16Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run alágbára wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónàigbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlúA ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sunkúnÀti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún
17Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàràNítorí èmi yóò la àárin yín kọjá,”ni OLÚWA wí.
18Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́nítorí ọjọ́ OLÚWAkí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ OLÚWA?Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́
19Yóò dàbí ọkùnrin tí ó sá láti ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.Tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu ẹkùnyóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọtí ó simi lé ògiri ilé rẹ̀tí ejò sì bù ú ṣán.
19
20Ǹjẹ́ ọjọ́ OLÚWA kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?Tí ó sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀
20
21“Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àṣè ẹ̀sìn in yínÈmi kò sì ní inú dídùn sí àpèjọ yín
22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ọrẹ sísun àti ọrẹ ọkà wáÈmi kò ní tẹ́wọ́n gbà wọ́nBí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.Èmi kò ní náání wọn.
23Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìnÈmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
24Jẹ́ kí òtítọ́ ṣàn bí odòàti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ
24
25ⓐ “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wání ogójì ọdún ní ihà ìwọ ilé Ísírẹ́lì?
26Ẹ̀yin ń gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yínibùgbé àwọn òrìṣà yínàní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
27Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Dámásíkù,”ni OLÚWA wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.