1Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run fi hàn mí: Ó pèsè ọwọ́ esú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀.
2Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “OLÚWA Ọlọ́run, mo bẹ̀ ọ́, dáríjìn! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
3OLÚWA ronúpìwàdà nípa èyí;
4Èyí ni ohun ti OLÚWA Ọlọ́run fi hàn mí: OLÚWA Ọlọ́run ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.
5Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “OLÚWA Ọlọ́run jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jákọ́bù yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
6OLÚWA ronúpìwàdà nípa èyí.
7Èyí ni ohun tí ó fi hàn mí: OLÚWA dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn-ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀.
8OLÚWA sì bi mi pé, “Ámósì, kí ni ìwọ rí?”
9
10Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé: “Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.
11Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ:
12Nígbà náà ni Ámásáyà sọ fún Ámósì pé “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Júdà. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀ ki o sì sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.
13Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Bẹ́tẹ́lì nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹ́ḿpìlì ìjọba rẹ̀.”
14Ámósì dá Ámásáyà lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùsọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.
15Ṣùgbọ́n OLÚWA mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́tẹ̀ fun àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’
16Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ ọ̀rọ̀ OLÚWA. Ìwọ wí pé,
17“Nítorí náà, èyí ni ohun ti OLÚWA wí: