Ìwé Wòlíì Ámósì 8:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run fi hàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n.

2Ó béèrè pé, “Ámósì kí ni ìwọ rí.” Nígbà náà ni OLÚWA wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.”

2Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”

3OLÚWA Ọlọ́run wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹ́ḿpìlì yóò yí padà sí ohùnréré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú-ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

4Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ talákà di ilẹ

5Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òṣùnwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ

6Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn talákà kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀

7OLÚWA ti fi ìgbéraga Jákọ́bù búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọkan nínú ohun tí wọ́n ṣe.

8“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí? Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha sọ̀fọ̀? Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Náílì, yóò sì ru ú sókè pátapáta bí ìkún omi a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Éjíbítì.

9“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí, “Èmi yóò mú òòrùn wọ̀ ní ọ̀sán, Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀ṣán gangan.

10Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀, gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún. Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí a sì fá orí i yín. Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí a bí àti opin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

10

11“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òùngbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA.

12Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti òkun dé òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúṣù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ OLÚWA ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

13“Ní ọjọ́ náà “àwọn arẹwà wúndíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin yóò dákú fún òùngbẹ omi.

14Àwọn tí ó fi òrìṣà Samaríà búra tí wọ́n wí pé, ‘tí wọ́n sì wí pé, ìwọ Dánì, ọlọ́run rẹ ń bẹ láàyè,’ àti bi ó ti dájú pé ọlọ́run Báṣébà ti ń bẹ láàyè àní, wọn yóò ṣubú, wọn kì yóò sì tún dìde mọ́.’ láàyè ìwọ Dánì.’ Bí ó ti dájú pè ọlọrun rẹ ń bẹ láàyè ìwọ Báṣébà Wọ́n yóò ṣubú, Wọn kì yóò si tún díde mọ.”

>