Ìwé Wòlíì Ámósì 9:1-15 BYB2014 - Bible AI

1Mo rí OLÚWA, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó sẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, Ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé Ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.

2Bí wọ́n tilẹ wa ilẹ lọ sí ìpò òkú Láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.

3Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Kámẹ́lì, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìṣàlẹ̀ òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.

4Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í se fún rere.”

4

5OLÚWA, Ọlọ́run Alágbára Ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ìlẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì sọ̀fọ̀ Gbogbo orílẹ̀ èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Náìlì ti wọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Éjíbítì.

6Òun ni ẹni tí ó kọ́ itẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé Ẹni ti ó pe àwọn omi òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé OLÚWA ni orúkọ rẹ̀.

6

7“Àbá ẹyin ọmọ Ísírẹ́lì kò ha dàbí àwọn ọmọ Kúsì sí mi?” ni OLÚWA wí. “Èmi kò ha ti mú Ísírẹ́lì gòkè láti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá àti àwọn Fílístínì láti ilẹ̀ Káfítórì àti àwọn Árámú láti kírì?

7

8“Dájúdájú, ojú OLÚWA Ọlọ́run ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀ Ṣíbẹ̀ Èmi kò ni pa ilé Jákọ́bù run pátapáta,” ni OLÚWA wí.

9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Ísírẹ́lì ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè bí a ti ń jọ ọkàn nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

10Gbogbo àwọn ẹlẹ́sẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́? A mú Ísírẹ́lì padà bọ̀ sípò.

11ⓐ “Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dáfídì tí ó wó ró Èmi yóò mọ odi rẹ̀ tí ó wó Èmi yóò sì sọ ahoro rẹ̀ di ìlú Èmi yóò sì kọ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀

12kí wọn le jógun ìyókù Édómù àti gbogbo orílẹ̀ èdè ti ń jẹ́ orúkọ mi,” ni OLÚWA, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

13ⓑ “Ọjọ́ náà ń bọ,” ni OLÚWA wí, “Tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀ Tí yóò sì ṣàn láti ara àwọn òkè kékèké.

14Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Ísírẹ́lì ènìyàn mi padà bọ̀ Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn Wọn yóò sì gbin àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì se ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn

15Èmi yóò gbin Ísírẹ́lì sí orí ilẹ̀ rẹ̀. A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,” ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ wí.

>