1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ ní wá wí pé:
2“Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Ísírẹ́lì.
3Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ orísìírísìí wa si Lẹ́bánónì o sì mu ẹ̀ka igi Kédàrì tó ga jùlọ
4O gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, o mu un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn ọlọ́jà.
5“ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò.
6Ó dàgbà, ó sì di àjàrà to kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú si i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o di àjàrà ó sì mu ẹ̀ka àti ewe jáde.
7“ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ Idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ kí ó le fún-un ni omi.
8Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’
9“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.
10Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”
11Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mi wá pé:
12“Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.
13Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà.
14Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró.
15Ṣùgbọ́n Ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran aṣojú lọ sí Éjíbítì, kí wọn bá à lè fún-un ni ẹsin àti àwọn ọmọ ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyorí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò wá da májẹ̀mú kó sì bọ́ níbẹ̀ bí?
16“ ‘Bí mo ti wà láàyè ni OLÚWA Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí.
17Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Fáráò pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún-un lójú ogun.
18Nítorí pé ó kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kò ní i bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan to ṣe yìí.
19“ ‘Nítorí náà OLÚWA Ọlọ́run wí pé: Bí mo ti wà láàyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀.
20Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, N ó mú ọ lọ Bábílónì láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi.
21Gbogbo ìsáǹsá àti ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi OLÚWA lo sọ̀rọ̀.”
22“ ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lori igi Kédàrí gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó sẹ̀sẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí.
23
24Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi OLÚWA ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkurú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.