1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:
2
3“Bí mo ti wà láàyè ni OLÚWA Ọlọ́run wí, ẹ̀yin kó ni i pa òwe yìí mọ́ ni Ísírẹ́lì.
4
5
6
7
8
9
10“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀
11(bó tilẹ̀ jẹ́ pé baba rẹ kò se irú rẹ̀):
12
13
14“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe bẹ́ẹ̀:
15
16
17
18Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
19“Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.
20Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn.
21“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.
22A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè
23Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní OLÚWA wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?
24“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
25“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, ‘OLÚWA kò ṣe é da kò tọ́.’ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì: se ọ̀nà mi ni kò tọ́? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́?
26Bí ènìyàn rere ba yípadà kúrò nínú ìwà rere rẹ̀, tó sì dẹ́sẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹsẹ tó ti dá.
27Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti se, tó si ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mi rẹ̀ là.
28Nítorí pé ó ronu lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítootọ́ ni yóò yè; kò sí ní i kú
29Síbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì wí pé, ‘Ọ̀nà OLÚWA kò tọ́.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí Ilé Ísírẹ́lì? Kì í wa se pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko tọ?
30“Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín.
31
32