1Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ mi wá:
2“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jérúsálẹ́mù, kí o sí wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ Ísírẹ́lì.
3Kí ó sì sọ fún un: ‘Èyí yìí ni OLÚWA sọ: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárin yín.
4Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúsù títí dé àríwá.
5Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi OLÚWA ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’
6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.
7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”
8Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá:
9“Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní OLÚWA wí:
10
11
12
13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Júdà èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ ṣíwájú mọ́ ńkọ́? Ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’
14
15
16
17
18Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ mi wá:
19“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
20La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi.
21Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.
22Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
23Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.
24“Nítorí náà èyíí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn.
25“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ aládé Ísírẹ́lì, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góngó,
26Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀,
27Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fifún.’
28
29
30
31
32