1
2Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí àwọn ará Ámónì kí ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ sí wọn.
3Sì wí fún àwọn ará Ámónì pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run tí ó wí pé: Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Júdà, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,
4kíyèsí i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ: wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.
5Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.
6Nítorí báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì
7nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.
8
9nítorí náà Èmi yóò sí Móábù sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Bétjẹ́símótì, Báálì-Méónì àti Kíríátaímù.
10Èmi yóò fi Móábù pẹ̀lú àwọn ará Ámónì lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn ní ìní, kí a má bà á lè rántí àwọn ará Ámónì láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo;
11Èmi yóò sì mú ìdájọ́ ṣsẹ sí Móábù lára, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.’ ”
12
13nítorí náà báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Édómù èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi sófo láti Temanì dé Dédánì yóò ti ipa idà ṣsubú.
14Èmi yóò gbẹ̀san lára Édómù láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì, wọn sì se ṣsi Édómù gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi: wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”
15
16nítorí náà báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí pé: Èmi ti ṣetán láti na ọwọ́ mi jáde sí àwọn ará Fílísítíà Èmi yóò sì ké àwọn ará Kérétì kúrò, Èmi yóò sì pa àwọn tí ó kù ní etí kún run.
17Èmi yóò sì gbẹ̀san ńlá lára wọn nípa ìbáwí gbígbóná; wọn yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi ni OLÚWA. Nígbà tí èmi yóò gba ẹ̀san lára wọn.’ ”