1
2“Ọmọ ènìyàn, nítorí pé Tírè sọ nípa Jérúsálẹ́mù pé, ‘Áà! A fọ́ èyí tí í ṣe bodè àwọn orílẹ̀-èdè, a yí i padà sí mi, èmi yóò di kíkún, òun yóò sì di ahoro,’
3nítorí náà, báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmí dojú kọ ọ́ ìwọ Tírè, Èmi yóò sì jẹ́ kí orílẹ̀ èdè púpọ̀ dide sí ọ, gẹ́gẹ́ bí òkun tíi ru sókè.
4Wọn yóò wó odi Tírè lulẹ̀, wọn yóò sì wo ilé ìṣọ́ rẹ̀ lulẹ̀; Èmi yóò sì ha ẹrùpẹ̀ rẹ̀ kúrò, Èmi yóò sì sọ ọ́ di orí àpáta.
5Yóò sì jẹ́ ibi nína àwọ̀n tí wọn fi ń pẹja sí láàárin òkun, ní OLÚWA Ọlọ́run wí. Yóò di ìkógun fún àwọn orílẹ̀ èdè.
6Ìlú tí ó tẹ̀dó sí, ní àárin gbùngbùn ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó fi idà sọ ọ́ di ahoro. Nígbà náà ní wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.
7“Nítorí báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, Ọba àwọn Ọba, dide sí Tírè pẹ̀lú ẹsin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun.
8Yóò sì fi idà ṣá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkítì tì ọ́, yóò sì gbé apata sókè sí ọ.
9Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀.
10Àwọn ẹsin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti o di fífọ́ pátapáta.
11Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀.
12Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú òkun.
13
14Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí èmi OLÚWA ti sọ ọ̀rọ̀ ní OLÚWA Ọlọ́run wí.
15“Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí sí Tírè: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń sẹlẹ̀ ní inú rẹ?
16
17Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:
18
19“Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́,
20nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ ibi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè.
21Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì sí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, ṣíbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní OLÚWA Ọlọ́run wí.”