Ìwé Wòlíì Ísíkẹ́lì 27:1-36 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:

2“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tírè.

3Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí:

3“ ‘Ìwọ Tírè wí pé “Ẹwá mi pé.”

4Ààlà rẹ wà ní àárin òkun; àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.

5Wọn ti fi pákó firi ti Sénárì kan gbogbo ọkọ̀ rẹ, wọ́n ti mú kédárì ti Lébánónì wá láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.

6Nínú igi Oákù ti Báṣánì ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ òbèlè rẹ̀; ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú igi bókísì láti erékùsù Kítímù wá

7Asọ funfun dáradára tí a fi abẹ́rẹ́ ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára láti Éjíbítì wá ni èyí tí ìwọ ta láti se okun ọkọ̀ aṣọ aláró àti elésèé àlùkò láti erékùṣù ti Èlíṣà ni èyí tí a fi bò ó

8Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè, tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ.

9Àwọn àgbà Gíbálì, àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀, wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ, gbogbo ọkọ̀ ojú òkun àti àwọn atukọ̀-òkun wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

9

10“ ‘Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútì wà nínú jagunjagun rẹ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ. Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn ró sára ògiri rẹ, wọn fi ẹwà rẹ hàn.

11Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékì wà lórí odi rẹ yíká; àti àwọn akọni Gámádì, wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ. Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ; wọn ti mú ẹwà rẹ pé.

12“ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

13“ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.

14“ ‘Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ.

15“ ‘Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀; wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ.

16“ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17“ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18“ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.

19“ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.

20“ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21“ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.

22“ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23“ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.

24Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25“ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èrò ní ọjà rẹ a ti mú ọ gbilẹ̀ a sì ti ṣe ọ́ lógo ní àárin gbungbun òkun

26Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ wá sínú omi ńlá. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ ní àárin gbùngbùn òkun.

27Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ, àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ. Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ tí ó wà ní àárin rẹ yóò rì sínú àárin gbùngbùn òkun ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28Ilẹ̀ etí òkun yóò mì nítorí ìró igbe àwọn atọ́kọ̀ rẹ.

29Gbogbo àwọn alájẹ̀ àwọn atukọ̀ àti àwọn atọ́kọ̀ ojú òkun; yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn, wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.

30Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ wọn yóò sì sunkún kíkorò lé ọ lórí wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.

31Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ wọn yóò wọ aṣọ yíya wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú ìkoro ọkàn nítorí rẹ pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.

32Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùn réré ẹkún fún ọ wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé: “Ta ni ó dàbí Tírè èyí tí ó parun ní àárin òkun?”

33Nígbà tí ọjà títà rẹ ti òkun jáde wá ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè lọ́rùn ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.

34Ní ìsinsìn yìí tí òkun fọ ọ túútúú nínú ibú omi; nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ní àárin rẹ, ni yóò ṣubú.

35Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé ní erékùṣù náà sí ọ àwọn ọba wọn yóò sì dìjì, ìyọnu yóò sì yọ ní ojú wọn.

36Àwọn oníṣòwò láàrin àwọn orílẹ̀ èdè dún bí ejò sí ọ ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”

icle>