Ìwé Wòlíì Ísíkẹ́lì 30:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá: wí pé:

2“Ọmọ ènìyàn, ṣọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí:

2“ ‘Pohùnréré ẹkún kí o sì wí pé, “Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”

3Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsí àní ọjọ́ OLÚWA sún mọ́ tòsí Ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú, àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà

4Idà yóò wá sórí Éjíbítì ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kúṣì Nígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítì wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.

5Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.

6“ ‘Èyí yìí ní OLÚWA wí: “ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Mígídólì títí dé Ásúwánì wọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ; ní OLÚWA Ọlọ́run wí:

7Wọn yóò sì wà lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro, ìlú rẹ yóò sì wà ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.

8Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA, nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítì tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.

9“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.

10“ ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Éjíbítì láti ọwọ́ Nébukadinésárì ọba Bábílónì.

11Òun àti àwọn ológun rẹ̀ ẹ́rù àwọn orílẹ̀-èdè ní a o mú wá láti pa ilẹ náà run. Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Éjíbítì ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.

12Èmi yóò mú kí àwọn odò Náílì gbẹ Èmi yóò sì ta ilẹ náà fún àwọn ènìyàn búburú: láti ọwọ́ àwọn àjòjì ènìyàn Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.

12Èmi OLÚWA ni ó ti sọ ọ́.

13“ ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère òrìṣà gbígbẹ́ ni Nófì kò ní sí ọmọ aládé mọ́ ní Éjíbítì, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.

14Èmi yóò sì mú kí Pátírọ́sì di ahoro èmi yóò fi ina sí Sóánì èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tébésì

15Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pélúsíómù ìlú odi Éjíbítì èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Jépésì kúrò

16Èmi yóò ti iná bọ Éjíbítì Pélúsíómù yóò japoró ní ìrora Èfúùfù yóò jà ní Tébésì Mémìfísì yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo

17Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Hẹ́lópónísè àti Búbásítì yóò ti ipa idà subú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn

18Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tápárebì nígbà tí mo bá já àjàgà Éjíbítì kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùukùu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

19Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Éjíbítì, wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.’ ”

20Ní ọjọ́ keje osù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá:

21“Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣe apa Fáráò Ọba Éjíbítì. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a ko sì ti di i si àárin igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú.

22Nítorí náà, báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi lòdì sí Fáráò Ọba Éjíbítì. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀.

23Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Éjíbítì ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀.

24Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Fáráò, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a ṣá ní àṣápa.

25Èmi yóò mú kí apá Ọba Bábílónì lé, ṣùgbọ́n apá Fáráò yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò sì fí idà náà kọlu Éjíbítì.

26Èmi yóò fọ́n àwọn ara Éjíbítì ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárin orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”

icle>