Ìwé Wòlíì Ísíkẹ́lì 31:1-18 BYB2014 - Bible AI

1Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹ́ta ọdún kọkànlá, ọrọ OLÚWA tọ̀ mí wá:

2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún Fáráò Ọba Éjíbítì àti sí ìjọ rẹ̀:

2“ ‘Ta ní a le fi wé ọ ní ọlá ńlá?

3Kíyèsí Ásíríà, tí ó jẹ́ òpépé igi ni Lébánónì ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣe ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.

4Omi mú un dàgbà sókè: orísun omi tí ó jìnlẹ̀ mú kí o dàgbà sókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.

5Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; Ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i: àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

6ⓐ ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko ìgbẹ́ ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀ èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìjì rẹ̀.

7Ọlá ńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.

8ⓑ Àwọn òpépé igi nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bá a dọ́gba, tàbí kí àwọn igi firi ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ẹwà rẹ̀ ṣe déédé pẹ̀lú rẹ̀.

9Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Édẹ́nì tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.

10“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ńi OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí; Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn kọ́, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga,

11Mo fi lé alákóso àwọn orílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan,

12àwọn orílẹ̀ èdè àjòjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárin àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìjì rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.

13Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó subú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ wà ní àárin ẹ̀ka rẹ̀.

14Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárin àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

15“ ‘Èyí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jínjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lẹ́bánónì ní aṣọ, gbogbo igi ìgbẹ́ gbẹ dànù.

16Mo mú kí orílẹ̀ èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìṣàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Édẹ́nì, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lẹ́bánónì, gbogbo igi tí ó ní omi dáadáa ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀.

17Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ ìjì rẹ̀, àwọn àjòjì rẹ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.

18“ ‘Èwo lára igi Édẹ́nì ní a lè fi wé ọ ní dídán àti ọlá ńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Édẹ́nì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárin àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. “ ‘Èyí yìí ní Fáráò àti ìjọ rẹ̀, ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”

icle>