1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ́ mi wá:
2“Ọmọ ènìyàn, fí àsọtẹ́lẹ̀ tako olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì; sọ tẹ́lẹ̀ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Ègbé ni fún olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì tí ó ń tọ́jú ara wọn nìkan! Ṣé ó dára kí olùṣọ́ àgùntàn ṣaláì tọ́jú agbo ẹran?
3Ìwọ jẹ wàrà. O sì wọ aṣọ olówùú sí ara rẹ, o sì ń pa ẹran tí ó wù ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò tọ́jú agbo ẹran.
4Ìwọ kò ì tíì mú aláìlágbára lára le tàbí wo aláìsàn sàn tàbí di ọgbẹ́ fún ẹni tí o fi ara pa. Ìwọ kò í tíì mú aṣàko padà tàbí wá ẹni tí ó nù. Ìwọ ṣe àkóso wọn ní ọ̀nà lílé pẹ̀lú ìwà òǹrorò.
5
6Àgùntàn mi n rin ìrìn àrè kiri ní gbogbo àwọn òkè gíga àti òkè kékeré. A fọ́n wọn ká gbogbo orí ilẹ̀ ẹni kankan kò sì wá wọn.
7“ ‘Nítorí náà, ìwọ olùṣọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA:
8Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, nitorí pé agbo ẹran mi kò ní olùṣọ́ àgùntàn nítorí tí a kọ̀ wọ́n, tì wọ́n sì di ìjẹ fún ẹranko búburú gbogbo àti pé, nítorí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn mi kò ṣe awárí agbo ẹran mi, ṣùgbọ́n wọn ń ṣe ìtọ́jú ara wọn dípò ìtọ́jú agbo ẹran mi,
9nítorí náà, ẹyin olùsọ́ àgùntàn, gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA:
10Èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi ṣe ìlòdì sí àwọn olùsọ́ àgùntàn, èmi yóò sì bèèrè agbo ẹran mi lọ́wọ́ wọn. Èmi yóò sì mú wọn dẹ́kun àti máa darí agbo ẹran mi, tí àwọn olùsọ́ àgùntàn náà kò sì ní lè bọ́ ara wọn mọ́. Èmi yóò gba agbo ẹran mi kúrò ni ẹnu wọn, kì yóò sì jẹ́ oúnjẹ fún wọn mọ́.
11“ ‘Nítorí èyí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi fúnra mi yóò wá àgùntàn mi kiri, èmi yóò sì ṣe àwárí wọn.
12Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe fojú tó agbo ẹran rẹ̀ tí ó fọ́n ká nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò se fojú tó àgùntàn mi. Èmi yóò gbá wọn kúrò ni gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ni ọjọ ìkúukùu àti òkùnkùn.
13Èmi yóò mú wọn jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò sì kó wọn jọ láti inú àwọn ìlú, èmi yóò sì mú wọn wá sí ilẹ ara wọn. Èmi yóò mú wọn jẹ ni orí àwọn òkè gíga Ísírẹ́lì, ni àárin àwọn òkè àti ní gbogbo ibùdó ilẹ̀ náà.
14Èmi yóò ṣe ìtọ́jú wọn ní pápá oko tútù dáradára, àní orí àwọn òkè gíga ti Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ilẹ̀ ìjẹ koríko wọ́n. Níbẹ̀ wọn yóò dùbúlẹ̀ ní ilẹ ìjẹ koríko dídára, níbẹ̀ wọn yóò jẹun ní pápá oko tútù tí ó dara ní orí òkè ti Ísírẹ́lì.
15Èmi fúnra mi yóò darí àgùntàn mi, èmi yóò mú wọn dùbúlẹ̀, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.
16
17“ ‘Ní tìrẹ, agbo ẹran mi, èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn, àti láàrin àgbò àti ewúrẹ́.
18Ṣé oúnjẹ jíjẹ ní pápá oko tútù dídára kò tó yín! Ṣé ó jẹ́ dandan fún ọ láti fi ẹsẹ̀ tẹ pápá oko tútù rẹ tí ó kù? Ṣé omi tí ó tòrò kò tó fún yín ní mímu? Ṣe dandan ni kí ó fi ẹrẹ̀ yí ẹsẹ̀ yín?
19Ṣé dandan ni kí agbo ẹran mi jẹ́ koríko tí ẹ ti tẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọn sì mú omi tí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ wọn sọ di ẹrẹ̀?
20“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí fún wọn: Wòó, èmi fúnra mi yóò ṣe ìdájọ́ láàárin àgùntàn tí ó sanra àti èyí tí ó rù.
21Nítorí ti ìwọ sún síwájú pẹ̀lú ìhà àti èjìká, tí ìwọ sì kan aláìlágbára àgùntàn pẹ̀lú ìwo rẹ títí ìwọ fi lé wọn lọ,
22Èmi yóò gba agbo ẹran mi là, a kì yóò sì kò wọ́n tì mọ́. Èmi yóò ṣe ìdájọ́ láàrin àgùntàn kan àti òmíràn.
23
24Èmi OLÚWA yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ìránṣẹ́ mi Dáfídì yóò jẹ́ ọmọ aládé láàárin wọn. Èmi OLÚWA ní o sọ̀rọ̀.
25“ ‘Èmi yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn, èmi yóò sì gba ilẹ̀ náà kúrò lọ́wọ́ ẹranko búburú, kí wọn kí o lè gbé ní aṣálẹ̀, kí àgùntàn sì gbé ní inú igbó ní àìléwu.
26Èmi yóò bùkún wọn àti ibi agbègbè ti ó yí òkè mi ká. Èmi yóò rán ọ̀wààrà òjò ni àkókò; òjò ìbùkún yóò sì wà.
27Àwọn igi ìgbẹ́ yóò mú èso wọn jáde, ilẹ̀ yóò sì mu irúgbìn jáde; A óò sì dá ààbò bo àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ náà. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá já àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà àjàgà, tí mo sì gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó fi wọ́n ṣe ẹrú.
28Àwọn orílẹ̀ èdè kì yóò lè kó wọn ní ẹrú mọ́, àwọn ẹranko búburú kì yóò lè pa wọn mọ́. Wọn yóò gbé ni àìléwu, kò sì sí ẹni kankan tí yóò le dẹ́rù bà wọ́n.
29Èmi yóò pèsè ilẹ̀ ti o ní oríyìn fún èso rẹ̀ fún wọn, wọn kì yóò sì jìyà nípasẹ̀ ìyàn mọ́ ni ilẹ̀ náà tàbí ru ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀ èdè.
30Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn, èmi wà pẹ̀lú wọn àti pé, àwọn ilé Ísírẹ́lì jẹ́ ènìyàn mi, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.
31Ìwọ àgùntàn mi, àgùntàn pápá mi; ni ènìyàn, èmi sì ni Ọlọ́run rẹ; ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”