Ìwé Wòlíì Ísíkẹ́lì 4:1-17 BYB2014 - Bible AI

1“Nísinsìnyìí, Ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán Jérúsálẹ́mù sí orí rẹ̀.

2Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.

3Kí o sì fi páànù irin kan ṣe ògiri láàrin rẹ̀ àti ìlú yìí, dojú kọ ọ́, kí o sì gbógun tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Ísírẹ́lì.

4“Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dúbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

5Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

6“Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.

7Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.

8Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé.

9“Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.

10Wọn òṣùnwọ̀n ogún (20) ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.

11Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.

12Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”

13OLÚWA sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

14Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! kò rí bẹ́ẹ̀ OLÚWA Ọlọ́run! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsìnyìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

15Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò igbẹ ènìyàn.”

16Ó sì tún sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jérúsálẹ́mù. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ́ jẹ pẹ̀lú ìfọ̀kansọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú,

17nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

cle>