1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá:
2
3Òpin tí dé sí ọ báyìí n ó sì tú ìbínú mi jáde sí ọ, n ó dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ, ń ó sì san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.
4Ojú mi kò ní i dá ọ sì bẹ́ẹ̀ ni ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ṣùgbọ́n ń ó san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.
5“Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Àjálù, àjálù lórí àjálù ń bọ̀;
6Òpin ti dé! Òpin ti dé, ó ti dìde lòdì sí ọ. Ó ti dé!
7Ìparun ti dé sórí yín gbogbo, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àsìkò ti tó, ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé; kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
8Mo ṣetán láti tú ìbìnú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, n ó sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìwà ìríra rẹ.
9Ojú mi kò ní i dá ọ sí, ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ń o san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà ìwà àti gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi OLÚWA lo kọlù yín.
10“Ọjọ́ náà ti dé! O ti dé: Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tan ná, ìgbéraga ti sọ jáde!
11Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kú, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí ọrọ̀ ko si ohun ti o niye.
12Àsìkò náà ti tó; ọjọ́ náà tidé, kí ẹni tó n rajà má se yọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ki ontàjà má ṣe ṣọ̀fọ̀; torí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13Nítorí pé ontàjà kò ni ri ilé tó tà gbà níwọ̀n ìgbà ti awọ̀n méjèèjì bá wà láyé; torí ìran tó kan ènìyàn yìí kò ní yí padà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò gba ara rẹ̀ là.
14Bí wọn tilẹ̀ fọn fèrè ogun tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀, kò sẹ́ni tí yóò lọ ojú ogun, torí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn
15“Idà wà níta, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn wà nílé, idà yóò pa ẹní tó bá wà ní orílẹ èdè, àjàkálẹ̀-àrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà, wọn yóò sì wà lórí òkè bí i àdàbà inú àfonífojì, gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀, olúkúlùkù nítorí àìṣedédé rẹ̀.
17Gbogbo ọwọ́ yóò rọ, gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
18Wọn o wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀, ìtìjú yóò mù wọn, wọn ó sì fá irun wọn.
19Wọn ó dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn ó sì dàbí èérí ìdọ̀tí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná OLÚWA. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
20Wọn n ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀sọ́ wọn, tí ó lẹ́wà, wọn sì ti fi ṣe òrìṣà, wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀. Nítorí náà, ní o sọ àwọn ǹnkan wọ̀nyí di ohun èérí tabi ìdọ̀tí fún wọn.
21Èmi yóò sì fi àwọn ǹnkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àlejò àti fún àwọn ènìyàn búburú ayé, wọn ó sì sọ ọ di aláìmọ́.
22Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn, wọn ó sì sọ ibi iṣúra mi di aláìmọ́; àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀ wọn ó sì bà á jẹ́
23“Rọ ẹ̀wọ̀n irin, torí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
24Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè ti búburú rẹ pọ̀ jù gba ilé wọn; ń ó sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
25Nígbà tí ìpayà bá dé, wọn ó wá àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò ní sí
26Wàhálà lórí wàhálà yóò dé, ìdágìrì sókè lórí ìdágìrì, Nígbà náà ni wọn ó wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì; ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn alàgbà.
27Ọba yóò sọ̀fọ̀, ọmọ aláde yóò wà láì ní ìrètí ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn, nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLÚWA.”