1Ní ọjọ́ karùn-ún (5), oṣù kẹfà (6) ọdún kẹfà (6) bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júdà níwájú mi, ọwọ́ OLÚWA Ọlọ́run bà lé mi níbẹ̀.
2Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí o jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà.
3Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi nírun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, sí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi,
4Sì kíyèsíi, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀
5Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu ọ̀nà ibi pẹpẹ.
6Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe-ohun ìríra ńlá tí ilé Ísírẹ́lì ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ ó tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù yí lọ.”
7Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.
8Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
9Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí o rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.”
10Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n yà sára ògiri.
11Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.
12Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘OLÚWA kò rí wa; OLÚWA ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”
13Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun mìíràn tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
14Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu ọ̀nà ilé OLÚWA tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Támúrì.
15Ó sọ fún mi pé, “Ṣé o rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”
16Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé OLÚWA, lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì OLÚWA, wọn kọjú sí ìlà òòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún òòrùn ní apá ìlà òòrùn.
17Ó sì wí fún mi, “Ṣé o ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékéré ni fún ilé Júdà láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé ó tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn se n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn.
18Nítorí náà, ń o fi ìbínú bá wọn wí; n kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, n kò ní fetí sí wọn.”