1Ní ọdún àkọ́kọ́ Beliṣáṣárì ọba Bábílónì, Dáníẹ́lì lá àlá kan, ìran náà sì wá sí ọkàn an rẹ̀ bí ó ṣe ṣùn sórí ibùṣùn un rẹ̀, ó sì kọ àlá náà sílẹ̀.
2Dáníẹ́lì sọ pé, “Nínú ìran mi lóru mo wò ó, mo sì rí afẹ́fẹ́ ọ̀run mẹ́rin tí ó ń ru omi òkun ńlá sókè.
3
4
5“Mo sì tún rí ẹranko kejì, ó rí bí irú ẹranko ńlá kan tí ó ń gbé ilẹ̀ òtútù; bíárì. Ó gbé ara sókè ní apá kan, ó sì ní egungun ìhà mẹ́ta láàrin ẹ̀yìn in rẹ̀, wọ́n sì sọ fún un pé, ‘Dìde kí o sì jẹ ẹran tó pọ̀!’
6“Lẹ́yìn ìgbà náà, mo tún rí ẹranko kẹta ó rí bí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹranko náà ní ìyẹ́ bí i ti ẹyẹ ní ẹ̀yìn, ó sì ní orí mẹ́rin, a sì fún un ní agbára láti ṣe ìjọba.
7
8
9
10
11“Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó.
12A sì gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ẹranko yóòkù, ṣùgbọ́n a fún wọn láàyè láti wà fún ìgbà díẹ̀.
13
14
15“Ọkàn èmi Dáníẹ́lì, dàrú, ìran tí ó wá sọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.
16Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtúmọ̀ nǹkan wọ̀nyí.
17‘Àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí, ni ìjọba mẹ́rin tí yóò dìde ní ayé.
18Ṣùgbọ́n, ẹni mímọ́ ti ọ̀gá ògo ni yóò gba ìjọba náà, yóò sì jogún un rẹ títí láé àti títí láéláé.’
19“Nígbà náà, ni mo fẹ́ mọ ìtúmọ̀ òtítọ̀ ẹranko kẹrin, tí ó yàtọ̀ sí àwọn yóòkù, èyí tí ó dẹ́rù ba ni gidigidi, tí ó ní eyín irin àti èékánná idẹ, ẹranko tí ó ń run tí ó sì ń pajẹ, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tó kù mọ́lẹ̀.
20
21
22títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ ọ̀gá ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogun ìjọba.
23“Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yóòkù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.
24Ìwo mẹ́wàá ni ọba mẹ́wàá tí yóò wá láti inú ìjọba yìí. Lẹ́yìn tí wọn ní ọba mìíràn yóò díde, ti yóò yàtọ̀ sí tí àwọn ti ìṣáájú, yóò sì borí ọba mẹ́ta.
25
26“ ‘Ṣùgbọ́n àwọn onídàájọ́ yóò jókòó, nígbà náà ni a ó gba agbára rẹ̀, a ó sì pa á rùn pátapáta títí ayé.
27Nígbà náà, ni a ó gba ìjọba, agbára àti títóbi ìjọba rẹ̀ ní abẹ́ gbogbo ọ̀run, a ó sì fi fún àwọn ẹni mímọ́, àwọn ènìyàn ọ̀gá ògo. Ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba títí ayé, gbogbo aláṣẹ ni yóò máa ṣe ìgbọràn sí i, wọn yóò sì máa sìn ín.’
28“Báyìí ni àlá náà ṣe parí, ọkàn èmi Dáníẹ́lì sì dàrú gidigidi, nítorí èrò ọkàn mi yìí, ojú mi sì yípadà ṣùgbọ́n mo pa ọ̀ràn náà mọ́ ní ọkàn mi.”