1Ní ọdun kìn-ín-ní Dáríúsì ọmọ Áhásúérésì, ẹni tí a bí ní Médíà, òun ló jẹ ọba lórí ìjọba Bábílónì.
2Ní ọdun kìn-ín-ní ijọba rẹ̀, èmi Dáníẹ́lì fi iyè sí i láti inú ìwé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA tí wòlíì Jeremáyà, wá pé, àádọ́rin ọdún ni Jérúsálẹ́mù yóò fi wà ní ahoro.
3Nígbà náà, ni mo yípadà sí OLÚWA Ọlọ́run, mo bẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ààwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
4Mo gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé:
5Àwa ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búburú. Àwa ti hu ìwà búburú, a sì ti ṣe ọ̀tẹ̀, a ti yí padà kúrò nínú àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ̀.
6Àwa kò fetí sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ sí àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé àti àwọn baba wa, àti sí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà.
7“OLÚWA ìwọ ni olódodo, ṣùgbọ́n báyìí ìtìjú dé bá àwọn ènìyàn Júdà, àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù àti gbogbo Ísírẹ́lì ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti fọ́n wa ká sí nítorí àìsòótọ́ ọ wa sí ọ.
8Áà! OLÚWA, àwa àti àwọn ọba wa, àwọn ọmọ aládé, àti àwọn baba wa, ìtìjú dé bá wa nítorí àwa ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.
9OLÚWA Ọlọ́run wa ní àánú, ó sì ń dáríjì, bí àwa tilẹ̀ ti ṣe ọ̀tẹ̀ síi;
10Àwa kò gbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run wa, a kò sì pa àwọn òfin rẹ mọ́, èyí tí ó fún wa nípasẹ̀ àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
11Gbogbo Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ sí òfin rẹ, wọ́n ti yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, wọ́n kọ̀ láti ṣe ìgbọràn sí ọ.
12Ìwọ ti mú ọ̀rọ̀ tí o sọ sí wa sẹ àti lórí àwọn alákòóso wa, nípa mímú kí ibi ńlá bá wa, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí lábẹ́ ọ̀run, bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù yìí.
13Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Mósè bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ibi yìí ti dé bá wa, ṣíbẹ̀ a kò bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere OLÚWA Ọlọ́run wa, nípa yíyí padà kí a kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì mọ òtítọ́ ọ rẹ.
14OLÚWA kò jáfara láti mú ibi náà wá sórí wa, nítorí Olódodo ni OLÚWA Ọlọ́run wa nínú u gbogbo ohun tí ó ń ṣe; ṣíbẹ̀ àwa kò ṣe ìgbọ́ran sí i.
15“Ní ìsinsin yìí, OLÚWA Ọlọ́run wa, ẹni tí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, pẹ̀lú ọwọ́ agbára, tí ó fún ara rẹ̀ ní orúkọ tí ó wà títí di òní, a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe búrurú.
16OLÚWA, ní ìbámu pẹ̀lú ìwà òdodo rẹ, yí ìbínú àti ìrunú rẹ padà kúrò ní Jérúsálẹ́mù ìlú u rẹ, òkè mímọ́ rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àìṣedéédé àwọn baba wa ti mú Jérúsálẹ́mù àti ènìyàn rẹ di ẹ̀gàn fún gbogbo àwọn tí ó yí wọn ká.
17“Nísinsinyìí, Ọlọ́run wa, gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, nítorí i tìrẹ OLÚWA, fi ojú àánú wo ibi mímọ́ rẹ tí ó ti dahoro.
18Tẹ́ etí rẹ sílẹ̀, Ọlọ́run, kí o gbọ́; ya ojú ù rẹ sílẹ̀, kí o sì wo ìdahoro ìlú tí a ń fi orúkọ rẹ pè. Àwa kò gbé ẹ̀bẹ̀ wa kalẹ̀ níwájú u rẹ nítorí pé a jẹ́ olódodo, bí kò ṣe nítorí àánú ńlá rẹ.
19OLÚWA, fetí sílẹ̀! OLÚWA, Dáríjìn! OLÚWA, gbọ́ kí o sì ṣe é! Nítorí i tìrẹ, Ọlọ́run mi, má ṣe pẹ́ títí, nítorí ìlú rẹ àti àwọn ènìyàn rẹ ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọ lára.”
20Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ OLÚWA Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ.
21Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gébúrẹ́lì ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.
22Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Dáníẹ́lì, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.
23Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní gba àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò kí ìran náà sì yé ọ:
24“Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ ọ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan ẹni mímọ́ jùlọ.
25“Nítorí náà, mọ èyí pé: Láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jérúsálẹ́mù se, kí a sì tú un kọ́, títí ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀ṣẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.
26Lẹ̀yìn ọ̀ṣẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn alákòóso tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi: ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.
27