Ìwé Wòlíì Hábákúkù 3:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Àdúrà wòlíì Hábákúkù gẹ́gẹ́ bí sígónótì.

2OLÚWA mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹrú sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ OLÚWA ṣọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mímọ̀; ni ìbínú, rántí àánú.

3Ọlọ́run yóò wa láti Témánì, Ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Páránì ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, Ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ

4Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀; Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá, níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ; ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

6Ó dúró, ó sì mi ayé; ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrì a sì tú àwọn òkè-ńlá ayérayé ká, àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba: ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

7Mo rí àgọ́ Kúṣánì nínú ìpọ́njú àti àwọn ibùgbé Mídíanì nínú ìrora.

7

8Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, OLÚWA? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò síṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí òkun tí ìwọ fi ń gún ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlá rẹ?

9Ìwọ kò bo ọrun rẹ, o sì pè fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọfà ìwọ sì pín ayé níyà pẹ̀lú odò.

10Àwọn òkè-ńlá ri ọ wọn ṣì wárìrì àgbàrá òjò ń ṣàn án kọjá lọ; ibú ń ké ramúramù ó sì gbé irú omi sókè.

10

11Òòrùn àti Òṣùpá dúró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni ibùgbé wọn, pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ ọfà rẹ ni wọn yára lọ, àti ni dídán ọ̀kọ̀ rẹ ti ń kọ mànà.

12Ní ìrúnú ni ìwọ rin ilẹ̀ náà já, ní ìbínú ni ìwọ tí tẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè rẹ.

13Ìwọ jáde lọ láti tú àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, àti láti gba ẹni àmì òróró rẹ là; Ìwọ ti run àwọn olórí kúrò nínú ilẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, fifi ìpìlẹ̀ hàn títí dé ọrùn

14pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká: ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ talákà run ní kọ̀kọ̀.

15Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn òkun já, O tẹ òkun mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀, ìwọ fi àwọn ẹsin rẹ̀ rin òkun já, ó sì mu omi ńlá jáde okiki omi ńlá

15

16Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

17Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná, tí èso kò sí nínú àjàrà; tí iṣẹ igi olifi yóò jẹ́ àṣedànù, àwọn oko ki yóò sì mú oúnjẹ wá; tí a ṣi ke agbo ẹran kúrò nínú agbo, tí ki yóò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùsọ̀ mọ́,

18ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀, èmi o layọ nínú Olúwa èmi yóò sí máa yọ nińú Ọlọ́run ìgbàla mi.

18

19OLÚWA Ọlọ́run ni agbára mi, òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín, yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.

19Ṣi olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.

cle>