Ìwé Wòlíì Hósíà 11:1-12 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ “Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde wá láti Éjíbítì.

2Wọ́n rúbọ sí Báálì bí mo ṣe ń pe Ísírẹ́lì sí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi jìnnà sí i: wọn rúbọ sí báálímu, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.

3Lóòtọ́ mo kọ́ Éfúráímù pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn lára dá.

4Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.

4

5“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bí Ṣé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?

6Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnú odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fòpin sí gbogbo èrò wọn.

7Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi Bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ ọ̀gá-ògo júlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.

7

8“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lì Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù? Ọkàn mi yípadà nínú mi Àánú mi sì ru sókè

9Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ tàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoro Nítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrin yín, Èmi kò ni i wa nínú ìbínú

10Wọn yóò máa tẹ̀lé OLÚWA; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn.

11Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bi i ẹyẹ láti Éjíbítì bi i àdàbà láti Ásíríà Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni OLÚWA wí.

12Éfúráímù tí fi irọ́ yí mi ká ilé Ísírẹ́lì pẹ̀lú ẹ̀tàn. Ṣùgbọ́n Júdà sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run Ó sì ṣe olóòótọ́ sí Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

e>