Ìwé Wòlíì Hósíà 12:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́; Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́. Ó sì ń gbèrú nínú irọ́ Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ásíríà Ó si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì.

2OLÚWA ní ẹ̀sùn tí yóò fí kan Júdà yóò fìyà jẹ Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún-un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.

3Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

4Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀ Ó bá OLÚWA ní Bẹ́tẹ́lì Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,

5àní OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLÚWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀

6Ṣùgbọ́n ìwọ́ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; Di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de OLÚWA yín nígbà gbogbo.

7Oníṣòwò ń lo òṣùnwọ̀n èké Ó fẹ́ràn láti rẹ́nijẹ.

8ⓐ Éfúráímù gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́”

8

9“Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì

10Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”

10

11Gílíádì ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.

12Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù; Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwó ó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó.

13OLÚWA lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

14Ṣùgbọ́n Éfúráímù ti mú un bínú gidigidi; OLÚWA rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

e>