1Nígbà Éfúráímù bá ń ṣọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì,a gbé e ga ní Ísírẹ́lìṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀ṣùn pé ó ń sin òrìṣà Báálì, ó sì kú.
2Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnra wọnère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sígbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nàWọn ń sọ nípa àwọn ènìyànwọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn“Ènìyàn tí ń rúbọ fi ẹnuko àwọn màluu ni ẹnu.”
3Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkù òwúrọ̀,bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́,bí i èèpo ọkà tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakàbí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé.
4“Ṣùgbọ́n Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀,ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmikò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn èmi
5Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní ihàní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi
6Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹNígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéragaNígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.
7Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìúnÈmi yóò farapamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.
8Béárì igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbàÈmi yóò bá wọn jà bí?Èmi yóò sì fà wọ́n yabí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya.
8
9“A ti pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lìnítorí pé ìwọ lòdì sí mi ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.
10Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là?Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà,àwọn tí ẹ sọ pé,‘Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé’?
11Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́baNinú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò
12Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọgbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀
13Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá aṢùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́nNígbà tí àsìkò tó,ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.
13
14“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú.Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikúIkú, àjàkálẹ̀-àrùn rẹ dà?Isà okú, ìparun rẹ dà?
14“Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
15Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn láti ọ̀dọ̀ OLÚWA yóò wá,Yóò fẹ́ wá láti inú asálẹ̀orísun omi rẹ̀ yóò gbẹkànga rẹ̀ yóò gbẹpẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrùàti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀
16Ará Sámáríà gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn,nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn.Wọn ó ti ipa idà ṣubú;a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀,A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”