1Yípadà ìwọ Ísírẹ́lì sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
2ⓐ Ẹ gba ọ̀rọ̀ OLÚWA gbọ́, Kí ẹ sì yípadà sí OLÚWA. Ẹ sọ fún un pé: “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fí ètè wa sán-an fún ọ
3Asíríà kò le gbà wá là; A kò ní í gorí ẹsin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé ‘Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.’
3
4“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ wọn.
5Èmi o dàbí ìrì sí Ísírẹ́lì wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì yóò sì ta gbòngbò kédárì ti Lébánónì
6Àsẹ̀sẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, Didan ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi ólífì Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi sídà ti Lébánónì.
7Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lébánónì.
8Ìwọ Éfúráímù; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó daba! lóhùn, èmi o sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”