Ìwé Wòlíì Hósíà 5:1-15 BYB2014 - Bible AI

1“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetí sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín: Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mísípà Àwọ̀n ti a nà sìlẹ̀ lórí Tábórì

2Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn Gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,

3Mo mọ ohun gbogbo nípa Éfúráímù Ísírẹ́lì kò sì pamọ́ fún mi Éfúráímù, ní báyìí ó ti di alágbèrè Ísírẹ́lì sì ti díbàjẹ́

3

4“Iṣe wọn kò gbà wọ́n láàyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà láàrin wọn kò sì mọ OLÚWA.

5Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí lé wọn; Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti Éfúráímù pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Júdà náà sì kọṣẹ̀ pẹ̀lú wọn.

6Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá OLÚWA, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrin wọn.

7Wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí OLÚWA wọ́n sì bí àwọn ọmọ àlè. Nísinsìn yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú pín wọn.

7

8“Fọn fère ní Gíbíà, kí ẹ sì fun ipè ní Rámà. Ẹ pariwó ogun ní Bẹti-Áfélì máa wárìrì, ìwọ Bẹ́ńjámínì.

9Éfúráímù yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì Mo sọ ohun tí ó dájú.

10Àwọn olórí Júdà dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi.

11A ni Éfúráímù lára, A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́ nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà

12Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Éfúráímù Mo sì dàbí ìdin sí ara Júdà.

12

13“Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀, tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná

14Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù, bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà. Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

15Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

>