Ìwé Wòlíì Hósíà 6:1-11 BYB2014 - Bible AI

1“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ OLÚWA ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa lára dá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.

2Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀

3Ẹ jẹ́ kí a mọ OLÚWA Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

5Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì. Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín

6ⓐ Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

7Bí i Ádámù, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi níbẹ̀.

8Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

9Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùbá de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣékémù, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.

10Mo ti rí ohun tó bani lẹ́rù ní ilé Ísírẹ́lì. Níbẹ̀ Éfúráímù, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Ísírẹ́lì sì di aláìmọ́.

10

11“Àti fún ìwọ, Júdà A ti yan ọjọ́ pẹ̀lú ìkórè rẹ

11“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

>