1Nígbà tí èmi ìbá mú Ísírẹ́lì láradá.Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúráímù ń farahànìwà búburú Ṣamáríà sì ń hàn sítaWọ́n ń ṣe èrúàwọn olè ń fọ́ iléàwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà
2Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pémo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátapátawọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
2
3“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
4Alágbèrè ni gbogbo wọnwọ́n gbóná bí ààrò àkàràtí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìnìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wawáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbónáó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààròwọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkísí,ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òruó sì bú jáde bí ọ̀wọ́ iná ní òwúrọ̀.
7Gbogbo wọn gbóná bí ààròwọ́n pa gbogbo olórí wọn run,gbogbo ọba wọn si ṣubúkò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
7
8“Éfúráímù ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;Éfúráímù jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ runṣùgbọ́n kò sì mọ̀,Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiribẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsíi
10Ìgbéraga Ísírẹ́lì ń jẹ́rìí sí iṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyíkò padà sí ọ̀dọ̀ OLÚWAỌlọ́run, tàbí kí ó wá a.
10
11“Éfúráímù dàbí àdàbàtó rọrùn láti tàn jẹ àti aláìgbọ́ntó wá ń pé Éjíbítì nísinsìn yìító sì tún ń padà lọ si Ásíríà.
12Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọnÈmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀runNígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀Èmi nà wọ́n bí ìjọ ènìyàn wọn ti gbọ́
13Ègbé ní fún wọn,nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!Ìparun wà lórí wọn,nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!Èmi yóò rà wọ́n padà.Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùn réré ẹkún lórí ibùsùn wọn.Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnìṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,ṣíbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá ògo;Wọ́n dàbí ọrun tí ó wà fún ìtànjẹ́Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubúnítorí irúnú ahọ́n wọn.Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣeẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Éjíbítì.