Ìwé Wòlíì Hósíà 8:1-14 BYB2014 - Bible AI

1“Ọlọ́run rẹ̀. Fi ìpè sí ẹnu rẹ! Ẹyẹ igún wà lórí ilé OLÚWA nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú, wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.

2Ísírẹ́lì kígbe pè mí ‘Áà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́!’

3Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀

4Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi wọ́n yan ọmọ aládé láì si ìmọ̀ mi nibẹ̀. Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe ère fún ara wọn, kì a ba le ké wọn kúrò.

5Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nù Ìbínú mi ń ru sí wọn: yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

6Ísírẹ́lì ni wọ́n ti wá! Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é Àní ère Samáríà, ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́.

6

7“Wọ́n gbin afẹ́fẹ́ wọ́n sì ká ìjì Igi ọkà kò lórí, kò sì ní mú oúnjẹ wá. Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà àwọn àlejò ni yóò jẹ.

8A ti gbé Ísírẹ́lì mì, Báyìí, ó sì ti wà láàrin àwọn orílẹ̀ èdè bí ohun èlò tí kò wúlò.

9Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Síríà gẹ́gẹ́ bí ẹhànnà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń rìn kiri. Éfúráímù ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárin orílẹ̀ èdè Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsìn yìí Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù lọ́wọ́ ìnílára ọba alágbára.

10

11“Nítorí Éfúráímù ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un

12Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn. Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì

13Wọ́n ń rúbọ tí wọ́n yàn fún mi, wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀ Ṣùgbọ́n inú OLÚWA kò dùn sí wọn. Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn yóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọn yóò padà sí Éjíbítì

14ⓐ Nítorí Ísírẹ́lì ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀ Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀ Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

>