Ìwé Wòlíì Jóẹ́lì 1:1-20 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó tọ Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì wá.

2Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbààgbà; ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà. Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?

3Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín, ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn, ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.

4Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù ní ọ̀wọ́ eṣú jẹ Èyí tí ọ̀wọ́ eṣú jẹ kù ní eṣú tata jẹ Èyí tí eṣú tata jẹ kù ni eṣú apanirun mìíràn jẹ

4

5Ẹ jí gbogbo ẹ̀yín ọ̀mùtí kí ẹ sì ṣunkún ẹ pohùnréré ẹkún gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì; ẹ pohùnréré ẹkún nítorí wáìnì tuntun nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.

6ⓐ Nítorí orílẹ̀ èdè kan ti sígun sí ilẹ̀ mìíràn ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà; ó ní eyín kìnnìún ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.

7Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò, ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di fun-fun.

7

8Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúndíá tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmúre, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.

9A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímú kúrò ní ilé OLÚWA; àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn ìrànṣẹ́ OLÚWA,

10Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń sọ̀fọ̀ nítorí, a fi ọkà ṣòfò: ọtí wáìnì tuntún gbé, òróró ń bùṣe.

11Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀; ẹ pohùn réré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà, nítorí àlìkámà àti nítorí ọkà báálì; nítorí ìkórè oko ṣègbé.

12Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pómégánátì, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi ápíílì, gbogbo igi igbó ni o rọ: Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn

13Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùn réré ẹkún ẹyín àlùfáà: ẹ pohùn réré ẹkún, ẹyín ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìrànsẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ jíjẹ àti ọrẹ mímú dúró ní ilé Ọlọ́run un yín.

14Ẹ yà ààwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé OLÚWA Ọlọ́run yín, kí ẹ sí képe OLÚWA

14

15A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ OLÚWA kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmare.

15

16A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá?

17Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn, a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀; nítorí tí a mú ọkà rọ.

18Àwọn ẹranko tí ń kerora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko; nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.

18

19OLÚWA, sí ọ ni èmi o ké pè, nítorí iná tí run pápa oko tútú ihà, ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó.

20Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú: nítorí tí àwọn iṣàn omi gbẹ, iná sí ti jó àwọn pápá oko ihà run.

e>