Ìwé Wòlíì Jónà 3:1-10 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Jónà wá nigbà kejì wí pé:

2“Dìde lọ sí Nínéfè, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”

3Jónà sì dìde ó lọ sí Nínéfè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA. Nínéfè jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.

4Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ̀n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Nínéfè wó.”

5Àwọn ènìyàn Nínéfè sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde ààwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ lati orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.

6Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Nínéfè, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú.

7Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Nínéfè pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́-ẹran tàbí agbo-ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi.

7“Kí a la Nínéfè já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbààgbà rẹ̀ pé:

8Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn.

9ⓐ Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”

10Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.