1Ṣùgbọ́n ó ba Jónà nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.
2
3Ǹjẹ́ báyìí, OLÚWA, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”
4Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”
5Jónà sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni ibòòji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.
6OLÚWA Ọlọ́run sì pesè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jónà; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jónà sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.
7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
8Ó sì ṣe, nígbà tí òòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jónà lórí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”
9Ọlọ́run sì wí fún Jónà pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”
10Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
11Ṣùgbọ́n Nínéfè ní jù ọ̀kẹ́-mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ilú ńlá náà?”