Ìwé Wòlíì Jeremáyà 10:1-25 BYB2014 - Bible AI

1Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ fún yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì.

2Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:

2“Má se tọ ọ̀nà àwọn orílẹ̀ èdè tàbí kí ẹ jẹ́ kí àmù òfuurufú dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀ èdè.

3Nítorí pé asán ni asà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣẹ́-ọnà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.

4Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́sọ̀ọ́. Wọ́n fi òòlù kàn án àti èṣo kí ó má ba à ṣubú.

5Wọ́n nàró bí igi ọ̀pẹ, òrìṣà wọn kò le è ṣọ̀rọ̀. Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé wọn nítorí pé wọn kò lè rìn. Má ṣe bẹ̀rù wọn; wọn kò le è ṣe ibi kankan bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

5

6Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ OLÚWA; o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.

7Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ Ọba àwọn orílẹ̀ èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀ èdè àti gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

8Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti òpè, wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò ní láárí

9Sílífà tí a ti kàn ni a mú wá láti Tásísì, àti wúrà láti Lépásì; èyí tí àwọn onísọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n kùn ní àwọ̀ aró àti eléṣé àlùkò, èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣẹ́.

10Ṣùgbọ́n OLÚWA ni Ọlọ́run tòótọ́, òun ni Ọlọ́run alààyè, Ọba ayérayé. Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì; orílẹ̀ èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.

11“Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kékèèké tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀, ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀, ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ tóbi síta nípa òye rẹ̀.

13Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkuùkù ru sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

13

14Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlóye àti aláìnímọ̀, ojú sì ti gbogbo alágbára pẹ̀lú ère rẹ̀, èrú ni ère rẹ̀, kò sì sí ẹ̀mí nínú wọn.

15Asán ni wọ́n, iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni; nígbà tí ìdájọ́ wọn bá dé, wọn yóò ṣègbé.

16Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jákọ́bù kò sì dàbí èyí, nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo àti Ísírẹ́lì tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀. OLÚWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.

17Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ìwọ tí o ń gbé ní abẹ́ ààbò.

18Nítorí èyí ni OLÚWA wí: “Ní àkókò yìí, èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”

18

19Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi! Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn, bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi, “Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”

20Àgọ́ mi bàjẹ́, gbogbo okùn rẹ̀ sì já. Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́ Kò sí ẹnìkankan pẹ̀lú mi mọ́, báyìí kò sí ẹni tí yóò ná àgọ́ mi tàbí ṣe ibùgbé fún mi

21Àwọn olùsọ́ àgùntàn jẹ́ aláìlóye, wọn kò sì wá OLÚWA: nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.

22Fetísílẹ̀; ariwo ìdàrúdàpọ̀ ńlá náà ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá, yóò sì sọ ìlú Júdà di ahoro àti ihò jàkùmọ̀

23Èmi mọ̀ OLÚWA wí pé ayé ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀, kì í ṣe fún ènìyàn láti gbe igbésẹ ara rẹ̀.

24Tún mi ṣe OLÚWA, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ. Kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.

25ⓐ Tú ìbínú rẹ síta sórí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò mọ̀ ọ́, sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jákọ́bù run, wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátapáta, wọ́n sì ti ba ilẹ̀ ibùgbé rẹ̀ jẹ́.

icle>