Ìwé Wòlíì Jeremáyà 17:1-27 BYB2014 - Bible AI

1“Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a fi ṣóóṣó irin kọ sílẹ̀ èyí tí ó hàn ketekete pẹ̀lú ẹnu ṣóróṣóró sí oókan àyà wọn, àti lórí àwọn ìwo tó wà lórí pẹpẹ wọn.

2Kódà àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ àti òpó Áṣérà lẹ́bàá igi tí ó tẹ́ rẹrẹ àti àwọn òkè gíga.

3Àwọn òkè nínú ilẹ̀ àti àwọn ọrọ̀ rẹ̀ àti ọlá rẹ̀ ni èmi yóò fi sílẹ̀ bí ìjẹ pẹ̀lú àwọn ibi gíga, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè yín.

4Láti ipaṣẹ̀ àìṣedéédé yín ni ẹ̀yin yóò ti sọ ogún tí mo fún un yín nù. Èmi yóò fi yín fún ọ̀tá yín bí ẹrú ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò mọ̀; nítorí ẹ̀yin ti mú inú bí mi, èyí tí yóò sì wà títí ayé.”

5Báyìí ni OLÚWA wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLÚWA

6Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ire, nígbà tí ó bá dé yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ ihà, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

6

7ⓐ “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, tí ó sì fi OLÚWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún-un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjáyà fún-un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

8

9Ọkàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè wòsàn, tani èyí lè yé?

9

10ⓑ “Èmi OLÚWA ń wo ọkàn àti èrò inú ọmọ ènìyàn láti ṣan èrè iṣẹ́ rẹ̀ fún-un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

10

11Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni ọ̀nà àìsòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀ ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

11

12Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní ibi ilé mímọ́ wa.

13OLÚWA olùgbẹ́kẹ̀lé Ísírẹ́lì gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì: gbogbo àwọn tí ó padà ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ ni a ọ́ kọ orúkọ wọn sínú ekuru, nítorí wọ́n ti kọ OLÚWA orísun omi ìyè wọn sílẹ̀.

13

14Wò mí sàn OLÚWA, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.

15Wọ́n sọ fún mi wí pé: “Níbo ni ọ̀rọ̀ OLÚWA wà? Jẹ́ kí ó di ìmúsẹ báyìí.” Ni OLÚWA wí.

16Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùsọ àgùntàn rẹ, ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú. Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.

17Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi, ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú

18Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn ó bẹ̀rù. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

19Èyí ni ohun tí OLÚWA wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn Ọba Júdà ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù.

20Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin Ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Júdà àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù tí ń wọlé láti ẹnu-bodè yìí.

21Báyìí ni OLÚWA wí ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù.

22Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.

23Ṣíbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ Ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí.

24Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsí láti gbọ́ tèmi ní OLÚWA wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ti ẹnu bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ náà.

25Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.

26Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Júdà àti ní agbègbè Jérúsálẹ́mù, láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti níbi òkè gúṣù láti orílẹ̀ èdè gíga. Wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti orẹ ọkà ẹran, ọrẹ ọpẹ́ tùràrí àti ìyìn wá sí ilé OLÚWA.

27Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ti ẹnu-bodè Jérúsálẹ́mù wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”

icle>