Ìwé Wòlíì Jeremáyà 21:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ Jeremáyà wá nígbà tí Ọba Sedekáyà rán Páṣúrì ọmọ Málíkíjà àti àlùfáà Sedekáyà ọmọ Mánásè síi; wọ́n wí pé:

2“Wádìí lọ́wọ́ OLÚWA fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá. Bóyá OLÚWA yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”

3Ṣùgbọ́n Jeremáyà dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekáyà,

4‘Èyí ni OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.

5Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle.

6Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-àrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú.

7OLÚWA sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn.’

8“Síwájú síi, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín.

9Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-àrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Bábílónì tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀.

10Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí níyà, ni OLÚWA wí. A ó sì gbé e fún Ọba Bábílónì, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’

11“Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé Ọba Júdà pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA.

12Ilé Dáfídì èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA sọ:

12“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀; yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára ẹni tí a ti jà lólè bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná. Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó láìsí ẹni tí yóò pa á.

13Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jérúsálẹ́mù ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì lórí olókúta tí ó tẹ́jú, Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojú kọ wá?”

14Èmi yóò jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni OLÚWA wí. Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀; ìyẹn yóò jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”

icle>