1“Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni OLÚWA wí.
2Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ ní ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín níyà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni OLÚWA wí.
3“Èmi OLÚWA tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi.
4Èmi ó wá olùṣọ́ àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni OLÚWA wí.
5
6
7“Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú OLÚWA wà láàyè tí ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.’
8Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú OLÚWA ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”
9Nípa ti àwọn wòlíì èké:
10
11
12
13
14
15Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA
16Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí,
17
18
19
20
21
22
23
24
25“Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’
26Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn?
27Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.
28Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni OLÚWA wí.
29“Ọ̀rọ̀ mi kò há a dàbí iná?” ni OLÚWA wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?
30“Nítorí náà, èmi lòdì sí àwọn wòlíì ni,” OLÚWA wí, “Tí ń jí ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá lò lọ́dọ̀ ara wọn.
31Bẹ́ẹ̀,” ni OLÚWA wí, “Èmi lòdì sí àwọn wòlíì tí wọ́n lo ahọ́n wọn káàkiri, síbẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ wí pé, ‘OLÚWA wí.’
32Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni OLÚWA wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi sìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni OLÚWA wí.
33“Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni OLÚWA wí.’
34Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.
35Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀: ‘Kí ni ìdáhùn OLÚWA?’ tàbí ‘Kíni ohun tí OLÚWA sọ?’
36Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ OLÚWA’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára alààyè padà.
37Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn OLÚWA sí ọ́?’ tàbí ‘Kí ni ohun tí OLÚWA bá ọ sọ?’
38Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ń sọ wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA,’ èyí ni ohun tí OLÚWA sọ: Ó ń lo ọ̀rọ̀ yìí, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún un yín láti má ṣe gbà á, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ OLÚWA.’
39Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín.
40Èmi yóò sì mú ìtìjú ayérayé wá sí orí yín, ìtìjú tí kò ní ní ìgbàgbé.”