1Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremáyà wá nípa àwọn ènìyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadinésárì Ọba Bábílónì.
2Nítorí náà, Jeremáyà wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Júdà àti sí àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù.
3Fún odidi ọdún mẹ́talélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Jòsáyà, ọmọ Ámónì Ọba Júdà, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, àmọ́ ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀.
4Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLÚWA ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀.
5Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.
6Má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”
7“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni OLÚWA wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”
8Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi,
9Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì,” ni OLÚWA wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀ èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátapáta, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé.
10
11Gbogbo orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì sìn ní Bábílónì ní àádọ́rin ọdún.
12“Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti orílẹ̀ èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni OLÚWA wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.
13Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ ani gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.
14Àwọn fúnra wọn yóò sì sin orílẹ̀ èdè púpọ̀ àti àwọn Ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
15
16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí mo fi ránṣẹ́ sí àárin wọn.”
17Mo sì gba aago náà lọ́wọ́ OLÚWA, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó rán mi sí mu ún.
18Jérúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà, àwọn Ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.
19Fáráò Ọba Éjíbítì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
20Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjòjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn Ọba Húsì, gbogbo àwọn Ọba Fílístínì, gbogbo àwọn ti Áṣíkélónì, Gásà, Ékírónì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Áṣídódì.
21Édómù, Móábù àti Ámónì
22Gbogbo àwọn Ọba Tirè àti Sídónì; gbogbo àwọn Ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá òkun.
23Dédánì, Témà, Búsì àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jínjìn réré.
24Gbogbo àwọn Ọba Árábíà àti àwọn Ọba àwọn àjòjì ènìyàn tí ń gbé inú ihà.
25Gbogbo àwọn Ọba Símírì, Élámù àti Mídíà.
26Àti gbogbo àwọn Ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jínjìn, ẹnìkìn-ín-ní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, Ọba Ṣéṣákì náà yóò sì mu.
27“Nígbà náà, sọ fún wọn: Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Mu, kí o sì mu amuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárin yín.
28Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba aago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún!
29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sọ.’
30“Nísinsinyìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:
31
32
33Nígbà náà, àwọn tí OLÚWA ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò sọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.
34
35
36
37
38