1Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Ọba Jehóáíkímù ọmọ Jòsáyà tí ń ṣe Ọba Júdà, ọ̀rọ̀ yìí wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA:
2“Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Dúró ní àgbàlà ilé OLÚWA, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé OLÚWA: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.
3Bóyá gbogbo wọn máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí ọ̀kọọkan wọn yóò kúrò nínú ìwà búburú wọn. Èmi ó yí ọkàn padà, n kò sì ní fi ibi tí mo ti rò sí wọn ṣe wọ́n.
4Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé síwájú yín.
5Àti tí ẹ kò bá fetísí àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò fetí sílẹ̀.
6Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”
7Àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jeremáyà tí ó sọ ní ilé OLÚWA.
8Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí OLÚWA pa láṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!
9Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLÚWA pé, ilé yìí yóò dàbí ṣílò, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremáyà nínú ilé OLÚWA.
10Nígbà tí àwọn aláṣẹ Júdà gbọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí, wọ́n lọ láti ààfin sí ilé OLÚWA, wọ́n sì mú àyè wọn, wọ́n jòkòó ní ẹnu ọ̀nà tuntun ilé OLÚWA.
11Àwọn àlùfáà àwọn wòlíì sọ fún àwọn aláṣẹ àti gbogbo ènìyàn pé, “Arákùnrin yìí gbọdọ̀ gba ìdájọ́ ikú nítorí pé ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ lórí ìlú yìí: bí ẹ̀yin ti fi etí yín gbọ́!”
12Nígbà náà ni Jeremáyà sọ fún gbogbo àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn wí pé: “OLÚWA rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé yìí àti ìlú yìí, gbogbo ohun tí ẹ ti gbọ́.
13Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. OLÚWA yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.
14Bí ó bá ṣe tèmi ni, èmi wà ní ọwọ́ yín, ẹ ṣe ohun tí ẹ̀yin bá rò pé ó dára, tí ó sì tọ́ lójú yín fún mi.
15Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni OLÚWA ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”
16Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ ogun.”
17Lára àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà sì sún ṣíwájú, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé,
18“Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:
19“Ǹjẹ́ Heṣekáyà Ọba Júdà tàbí ẹnikẹ́ni ní Júdà pa á bí? Ǹjẹ́ Heṣekáyà kò bẹ̀rù OLÚWA tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ OLÚWA kò há a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”
20(Bákan náà Úráyà ọmọ Ṣémáíà láti Kúríátì Jéárímù jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ OLÚWA. Ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremáyà ti ṣe.
21Nígbà tí Ọba Jéhóíákímù àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Úráyà gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Éjíbítì.
22Ọba Jéhóíákímù rán Elinátanì ọmọ Álíbórì lọ sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mìíràn.
23Wọ́n sì mú Úráyà láti Éjíbítì lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba Jéhóíákímù; ẹni tí ó fi idà pa, ó sì sọ òkú rẹ̀ sí inú isà òkú àwọn ènìyàn lásán.)
24Áhíkámù ọmọ Sáfánì ń bẹ pẹ̀lú Jeremáyà, wọn kò sì fi í lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti pa á.