Ìwé Wòlíì Jeremáyà 29:1-32 BYB2014 - Bible AI

1Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jérúsálẹ́mù sí àwọn tí ó yè nínú àwọn aṣàtìpó àti àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn Nebukadinésárì tí wọ́n ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì.

2Èyí ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀yìn ìṣèjọba Jéhóíákímù àti ayaba àti ìwẹ̀fà pẹ̀lú àwọn olórí Júdà àti Jérúsálẹ́mù, àwọn gbẹ́nà gbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù.

3Ó fi lẹ́tà náà rán Élásà ọmọ Híkáyà ti Ṣédà.

4Èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì:

5“Ó kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.

6Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fọ́kọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ síi ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá.

7Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ire ilẹ̀, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí OLÚWA fún ire ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”

8Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárin yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá.

9Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi; Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni OLÚWA wí.

10Báyìí ni OLÚWA wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jérúsálẹ́mù.

11Nítorí mo mọ ète tí mo ní fún un yín,” ni OLÚWA wí, “Ète láti mú yín lọ́rọ̀ láìpa yín lára, ète láti fún un yín ní ìrètí ọjọ́ iwájú.

12Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.

13Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni OLÚWA Ọlọ́run wí.

14Èmi yóò sì mú yín kúrò ní ìgbékùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè àti ibi gbogbo tí mo ti lé yín jáde. Èmi yóò sì kó yín padà sí Jérúsálẹ́mù ibi tí mo ti kó jáde lọ sí ilé àtìpó.”

15Ẹ lè sọ pé, “OLÚWA ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.”

16Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA nípa Ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú náà; àní àwọn ènìyàn ìlú yín tí kò lọ sí ilé àtìpó pẹ̀lú yín.

17Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí pé: “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn; Èmi yóò sọ wọ́n dà bí ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.

18Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni Èmi yóò fi lé wọn; Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, àti ohun ẹ̀gún àti ẹ̀rù; ohun ẹ̀gbin àti ohun ẹ̀dùn láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè ayé.

19Nítorí wọ́n kọ̀ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ni ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni OLÚWA Ọlọ́run wí.

20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin àtìpó, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.

21Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run sọ nípa Áhábù ọmọ Kóláháyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Máséà tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.

22Nítorí ti wọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Bábílónì láti Júdà: ‘Ọlọ́run yóò ṣe yín bí i Sedekáyà àti Áhábù tí Ọba Bábílónì dáná sun.’

23Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Ísírẹ́lì, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni OLÚWA wí.

24Wí fún Ṣemáyà tí í ṣe Neelamíyà pé,

25“Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,

26‘OLÚWA ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé OLÚWA, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.

27Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín?

28Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì.

30Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremáyà wá wí pé,

31“Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn àtìpó: ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ nípa Ṣemáyà àti Neelamaiti: Nítorí pé Semaíà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un yín, súgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.

32Nítorí pé, Èmi kò rán Ṣemáyà ní àṣọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ fún un yín, ó sì ti mú kí ẹ gba àṣọtẹ́lẹ̀ èké gbọ́. Èmi yóò fi ìyà jẹ Ṣemáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀. Kò sí ẹni tí yóò ṣẹ́kù nínú àwọn ìran rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí àwọn ohun rere tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi, nítorí ó ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, ni OLÚWA wí.’ ”

icle>