Ìwé Wòlíì Jeremáyà 35:1-19 BYB2014 - Bible AI

1Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ní ọjọ́ Jehóaikimu ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà wí pé:

2“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rékábù, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé OLÚWA, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

3Nígbà náà ni mo mu Jmanáyà ọmọ Jeremáyà, ọmọ Hábásínáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rékábù.

4Mo sì mú wọn wá sí ilé OLÚWA sínú iyàrá Hanani ọmọ Ígídálíà, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Mááséíà, ọmọ Sálúmù, olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà,

5Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rékábù. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

6Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jónádábù ọmọ Rékábù, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé

7Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbití ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’

8Báyìí ni àwa gba ohùn Jónádábù ọmọ Rékábù bàbá wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó palásẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa.

9Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn.

10Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́ràn, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jónádábù baba wa paláṣẹ fún wa.

11Ó sì se, nígbà tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Síríà.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jérúsálẹ́mù.”

12Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Jeremáyà wá wí pé:

13“Báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Júdà, àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni OLÚWA wí.

14‘Ọ̀rọ̀ Jónádábù ọmọ Rékábù tí ó pa láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú sẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími.

15Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísisiyìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sími.

16Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jónádábù ọmọ Rékábù pa òfin baba wọn mọ́ tí ó palásẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17“Nítorí náà, báyìí ni, OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Júdà, àti sórí gbogbo olùgbé Jérúsálẹ́mù nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18Nígbà náà ni Jeremáyà wí fún ìdílé Rékábù pé, “Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jónádábù baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó palásẹ fún un yín.’

19Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí, pé: ‘Jónádábù ọmọ Rékábù kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

icle>