Ìwé Wòlíì Jeremáyà 48:1-47 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ Nípa Móábù: Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ègbé ni fún Nébò nítorí a ó parun. A dójú ti Kíríátaímù, a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká.

2Móábù kò ní ní ìyìn mọ́, ní Héṣíbónì ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀ èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín.

3Gbọ́ igbe ní Horonáímù, igbe ìrora àti ìparun ńlá.

4Móábù yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta.

5Wọ́n gòkè lọ sí Lúhítì, wọ́n ń sunkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí Horonáímù igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ.

6Sá! Àsálà fún ẹ̀mí rẹ; kí o dàbí igbó ní aṣálẹ̀.

7Níwọ̀n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Sémọ́sì náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀.

8Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí OLÚWA ti sọ̀rọ̀.

9Fi iyọ̀ sí Móábù, nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀.

9

10“Ìfibú ni fún ẹni tí ó dúró láti ṣe iṣẹ́ OLÚWA, ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.

10

11“Móábù ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí. Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà.

12Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “nígbà tí n ó rán àwọn tí ó da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta; Wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀.

13Nígbà náà Móábù yóò sì tú u nítorí kémósì, bí ojú ti í ti ilé Ísírẹ́lì nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Bétélì.

13

14“Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘ajagun ni wá, alágbára ní ogun jíjà’?

15A ó pa Móábù run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀; a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,” ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun.

16“Ìṣubú Móábù súnmọ́; ìpọ́njú yóò dé kánkán.

17Ẹ dárò fún, gbógbó ẹ̀yin tí ó yí i ká gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó. Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’

17

18“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Díbónì, nítorí tí ẹni tí ó pa Móábù run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.

19Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní Áróà. Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà ‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’

20Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀, ẹ hu, sì kígbe síta! Ámónì kéde pé a pa Móábù run.

21Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéù sórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì,

22sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù

23sórí Kíríátaímù, Bẹti Gámù àti Bẹti Méónì,

24sórí Kéríótì àti Bóásì, sórí gbogbo ìlú Móábù, nítòsí àti ní ọ̀nà jínjìn.

25A gé ìwo Móábù kúrò, apá rẹ̀ dá,” ni OLÚWA wí.

25

26“Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá OLÚWA, jẹ́ kí Móábù pàfọ̀ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn.

27Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

28Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrin àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Móábù. Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò.

28

29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù: àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.

30Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni OLÚWA wí, “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkankan.

31Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí Móábù fún àwọn ará Móábù ni mo kígbe lóhùn rara Mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin Kíháráṣè.

32Mo sunkún fún ọ bí Jásì ṣe sunkún ìwọ àjàrà Síbínà. Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé òkun wọn, Ámónì, ajẹnirun ti kọlu èṣo rẹ àti àwọn èṣo àjàrà rẹ.

33Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko Móábù, mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúnni; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ti ayọ̀.

33

34“Ohùn igbe wọn gòkè láti Hésíbónì dé Élíà àti Jásì láti Sóà títí dé Hórónáímù àti Éjíbítì Sélíáyà, nítorí àwọn omi Nímírímù pẹ̀lú ti gbẹ

35Ní ti Móábù ni èmi yóò ti fi òpin sí ẹni tí ó rúbọ sí ibí gíga àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,” ni OLÚWA wí.

36“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Móábù bí fèrè oró Híhárésétì ìṣúra ńlá tí wọ́n kójọ ṣègbé.

37Gbogbo orí mi ni ó pá, gbogbo irungbọ̀n ni a gé kúrò, gbogbo ọwọ́ ni a ṣá lọ́gbẹ́, àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́.

38Ní gbogbo orílẹ̀ èdè Móábù àti ní ita kò sí ohun kan bí kò ṣe ọ̀fọ̀, nítorí tí mo fọ́ Móábù bí a ti ń fọ́ ohun elò tí kò wu ni,” ni OLÚWA wí.

39“Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni Móábù ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Móábù ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.”

40Báyìí ni OLÚWA wí: “Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí Móábù.

41Koríko kan yóò di kíkó àti àwọn ìlú olódì. Ní ọjọ́ náà ọkàn akọni Móábù yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí.

42A ó pa Móábù run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè nítorípé ó gbéraga sí OLÚWA.

43Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn Móábù,” ní OLÚWA wí.

44“Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí Móábù àní ọdún Ìjìyà rẹ,” ní OLÚWA wí.

44

45“Ní abẹ́ òjìji Hésíbónì àwọn tí ó sá dúró láìní olùrànlọ́wọ́ nítorí iná ti jáde wá láti Hésíbónì àti ọwọ́ iná láti àárin Síónì sì jó iwájú orí Móábù run àti agbárí àwọn ọmọ àlùfáà.

46Ègbé ní fún ọ Móábù! Wọn yóò sì kó àwọn ọmọkùnrin yín lọ sí ilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin yín lọ sí ìgbékùn.

46

47“Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ Móábù padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,” ni OLÚWA wí.

icle>